Egalitarian Voice
Online news outfit that comes with credible and factual news
Click Here
Our Commitment
We are committed to give latest news and update all over the world. We give valid news, events and occurence around the globe
Click Here
Previous
Next

Fact: ISÉ LOÒGÙN ÌSẸ́

Yorùbá bò wón ní “Àgbàlagbà tó bá fàárò seré yíó fojó alé gbàárù àti pé apálará”, “ìgúnpá ni ìyekan ènìyàn”.  Ìdí isé eni ni a tí ń moni lóle. Ìdí pàtàkì tí àwon ìpéde wònyín ń fi Ìdí  rè múlè ni pé,

Ìràn yorùbá féràn láti máa tepá mó isé.

Yorùbá kórìíra ìwà olè àti ìmélé

Láti kékeré ni yorùbá ti máa n fí esè omo won lé ònà isé àselà yálà nípasè ìlànà àjogúnbá isé ìdílé, ìlànà àwòse ló dò o elòmíràn, ìlànà ìsínnije tàbí nípa fífi omo se òfà (Ìwòfà).

Ní kété tí a bá ti bí mo sílé ayé ni àwon òbí omo ti máa ń se àyèwò lódò o ifá nípa síse ìsèntáyé/àkosèjayé e rè. Ìdí ni láti mo isé tí Elédàá yàn mó omo láti ode òrun. Yorùbá gbàgbó pé tí omo bá lo kósé mìíràn yàtò sí èyí, kó le lu àlùyo bí ó tiwù kí ó gbìyànjú tó. Ìdi niyi ti yorùbá fi máa ń wúre pé kí Olórun má jè é kí á se isé onísé.

ÌLÀNÀ TÍ À Ń GBÀ KÓ ISÉ

Isé àjogúnbá/Ídílé/Ìran

Èyí ni isé tí babańlá omo ń se. Irúfé isé yìí ti di isé ìrandíran. Láti kékeré ni omo ti ń fojú sí bí bàbà rè se ń se isé yìí. Bí omo bá se ń dàgbà si ni yíó máa kópa nínú isé yìí nípa ríran bàbá rè lówó.

Nígbà tí omó bá ti mo isé dájú, yíó máa sin bàbá a rè títí tí yíó fi dàgbà tó eni tí ń ya isé. Òpòlopò ìgbà ni Kìí sí ayeye ìgbàyònda ju wípé bàbá yíó wúre fún omo rè pé òun náà yíó rí omo sìn-ín.

Àwòse

Éyí máa ń wópò tí omo kò bá se Irúfé isé bàbá/ìdilé rè. Àwon òbí maá mú irú omo béè lo òdò Eni tí ô ń se irúfé isé tí ó wù ú Kó. Bàbá omo, ògá isé àti onídúúró yíó se àdéhùn iye odún tí omo náà ó lò ní òdò o won, iye owó isé àti àwon òfin tàbí ìlànà tí ó rò mó isé kíkó náà. Ayeye/Ìwúre ìgbàyònda máa ń wáyé ní òpin ìkósé.

Isin-in je

Èyí ni lílo ònà buru ko isé. Eni tí ó fé kó isé yíó máa dúró ti ògá isé bí Eni pé ó ń báa seré.  Yíó máa dógbón fojú sí i bí ó se ń se isé náà. Béè ni yíó máa se títí tí yíó fi mo gbogbo àsírí tí ó rò mó isé náà tí òun náà yíó sì le dá a dúró fún ara a re. Kìí si pé kí wón san owó ìkósé tàbí síse Ayeye ìgbàyònda.

Síse Ìwòfà

Ònà míràn tí a má ń gbà kó isé láyé àtijó ni nípa fífi ara Eni tàbí omo Eni se ofà. Ìwòfà ni Eni tí a fà sílè láti yá owó lówó o ayánilówó.  Ìwòfà yíó máa sisé sin ayánilówó. títí di àsìkò tí yíó rí owó tí ó yá san padà.

ALSO READ: Fact-Check: Is Lagos Truly No Man’s Land? Read the history

Ní gbogbo àsìkò yìí Ìwòfà yíó máa fi ojú sílè kó isé tí ń se títí tí yíó fi mó. Nígbà tí ó bá parí ofà a rè, ó le bèrè sí ń se isé tí ó tí mò náà.

Orísiirísi isé abínibí ni ó wà ní òde òní. Bí àwon kan se wà fún àwon obìnrin àti okùnrin lótòtò, béè gégé ni àwon mìíràn wà fún tako tabo lápapò.  Díè lára àwon isé abínibí ilè Yorùbá ni iwonyi; Isé agbe, Isé ìsègùn/iwosan, ise ode, ise ona, isé aso híhun, isé àyàn, ìkòkò mímo, isé ose síse abbl.

[AlawiyeBlog]

ALSO READ: We are reintroducing ‘history’ in basic school curriculum, FG says

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Related Articles

Segun Akinlabi

Media Blogger

EgalitarianVoice is a subsidiary of EGALITARIAN MEDIA HUB, it is a blog that keeps you up to date latest news and updates all around the world.

Our articles are written by real life geeks, seasoned and experienced authors.

The site is committed to secure your right cus your voice must be heard and advertisement of your products & services.

The site is managed by Egalitarian Segun AKINLABI who is the Editor-in-chief, others editors from Egalitarian Team Oyo State, Nigeria.

Egalitarian

Featured Posts
Advertisements