Yorùbá bò wón ní “Àgbàlagbà tó bá fàárò seré yíó fojó alé gbàárù àti pé apálará”, “ìgúnpá ni ìyekan ènìyàn”. Ìdí isé eni ni a tí ń moni lóle. Ìdí pàtàkì tí àwon ìpéde wònyín ń fi Ìdí rè múlè ni pé,
Ìràn yorùbá féràn láti máa tepá mó isé.
Yorùbá kórìíra ìwà olè àti ìmélé
Láti kékeré ni yorùbá ti máa n fí esè omo won lé ònà isé àselà yálà nípasè ìlànà àjogúnbá isé ìdílé, ìlànà àwòse ló dò o elòmíràn, ìlànà ìsínnije tàbí nípa fífi omo se òfà (Ìwòfà).
Ní kété tí a bá ti bí mo sílé ayé ni àwon òbí omo ti máa ń se àyèwò lódò o ifá nípa síse ìsèntáyé/àkosèjayé e rè. Ìdí ni láti mo isé tí Elédàá yàn mó omo láti ode òrun. Yorùbá gbàgbó pé tí omo bá lo kósé mìíràn yàtò sí èyí, kó le lu àlùyo bí ó tiwù kí ó gbìyànjú tó. Ìdi niyi ti yorùbá fi máa ń wúre pé kí Olórun má jè é kí á se isé onísé.
ÌLÀNÀ TÍ À Ń GBÀ KÓ ISÉ
Isé àjogúnbá/Ídílé/Ìran
Èyí ni isé tí babańlá omo ń se. Irúfé isé yìí ti di isé ìrandíran. Láti kékeré ni omo ti ń fojú sí bí bàbà rè se ń se isé yìí. Bí omo bá se ń dàgbà si ni yíó máa kópa nínú isé yìí nípa ríran bàbá rè lówó.
Nígbà tí omó bá ti mo isé dájú, yíó máa sin bàbá a rè títí tí yíó fi dàgbà tó eni tí ń ya isé. Òpòlopò ìgbà ni Kìí sí ayeye ìgbàyònda ju wípé bàbá yíó wúre fún omo rè pé òun náà yíó rí omo sìn-ín.
Àwòse
Éyí máa ń wópò tí omo kò bá se Irúfé isé bàbá/ìdilé rè. Àwon òbí maá mú irú omo béè lo òdò Eni tí ô ń se irúfé isé tí ó wù ú Kó. Bàbá omo, ògá isé àti onídúúró yíó se àdéhùn iye odún tí omo náà ó lò ní òdò o won, iye owó isé àti àwon òfin tàbí ìlànà tí ó rò mó isé kíkó náà. Ayeye/Ìwúre ìgbàyònda máa ń wáyé ní òpin ìkósé.
Isin-in je
Èyí ni lílo ònà buru ko isé. Eni tí ó fé kó isé yíó máa dúró ti ògá isé bí Eni pé ó ń báa seré. Yíó máa dógbón fojú sí i bí ó se ń se isé náà. Béè ni yíó máa se títí tí yíó fi mo gbogbo àsírí tí ó rò mó isé náà tí òun náà yíó sì le dá a dúró fún ara a re. Kìí si pé kí wón san owó ìkósé tàbí síse Ayeye ìgbàyònda.
Síse Ìwòfà
Ònà míràn tí a má ń gbà kó isé láyé àtijó ni nípa fífi ara Eni tàbí omo Eni se ofà. Ìwòfà ni Eni tí a fà sílè láti yá owó lówó o ayánilówó. Ìwòfà yíó máa sisé sin ayánilówó. títí di àsìkò tí yíó rí owó tí ó yá san padà.
ALSO READ: Fact-Check: Is Lagos Truly No Man’s Land? Read the history
Ní gbogbo àsìkò yìí Ìwòfà yíó máa fi ojú sílè kó isé tí ń se títí tí yíó fi mó. Nígbà tí ó bá parí ofà a rè, ó le bèrè sí ń se isé tí ó tí mò náà.
Orísiirísi isé abínibí ni ó wà ní òde òní. Bí àwon kan se wà fún àwon obìnrin àti okùnrin lótòtò, béè gégé ni àwon mìíràn wà fún tako tabo lápapò. Díè lára àwon isé abínibí ilè Yorùbá ni iwonyi; Isé agbe, Isé ìsègùn/iwosan, ise ode, ise ona, isé aso híhun, isé àyàn, ìkòkò mímo, isé ose síse abbl.
[AlawiyeBlog]
ALSO READ: We are reintroducing ‘history’ in basic school curriculum, FG says